Nah 2:1-13

Nah 2:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

ATUNIKA de iwaju rẹ (Ninefe): pa ile-iṣọ mọ, ṣọ ọ̀na na, di àmurè ẹ̀gbẹ rẹ ko le, mura girigiri. Nitori Oluwa tun pada si ọlanla Jakobu, gẹgẹ bi ọlanla Israeli: atunidanù ti tú wọn danù, nwọn si ba ẹka àjara wọn jẹ. A sọ asà awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ di pupa, awọn akin wọn wọ̀ odòdó: kẹkẹ́ ogun yio ma kọ bi iná li ọjọ ipèse rẹ̀, igi firi li a o si mì tìti. Ariwo kẹkẹ́ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọ̀na gbigbòro, nwọn o dabi etùfu, nwọn o kọ́ bi mànamána. On o ṣe aṣàro awọn ọlọla rẹ̀: nwọn o kọsẹ̀ ni irìn wọn; nwọn o yara si ibi odi rẹ̀, a o si pèse ãbo rẹ̀. A o ṣi ilẹ̀kun odò wọnni silẹ, a o si sọ ãfin na di yiyọ́. Eyi ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ li a o si dì ni igbèkun lọ, a o si mu u goke wá, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ yio fi ohùn bi ti oriri ṣe amọ̀na rẹ̀, nwọn a ma lù aiya wọn. Ṣugbọn Ninefe li ọjọ ti o ti wà bi adagun omi: sibẹ̀ nwọn o salọ kuro. Duro, duro! ni nwọn o ma ke; ṣugbọn ẹnikan kì yio wò ẹhìn. Ẹ ko ikogun fàdakà, ẹ ko ikogun wurà! ati iṣura wọn ailopin na, ati ogo kuro ninu gbogbo ohunelò ti a fẹ́. On ti sòfo, o ti di asan, o si di ahoro: aiyà si yọ́, ẽkún nlù ara wọn, irora pupọ̀ si wà ninu gbogbo ẹgbẹ́, ati oju gbogbo wọn si kó dudu jọ. Nibo ni ibugbé awọn kiniun wà, ati ibujẹ awọn ọmọ kiniun, nibiti kiniun, ani agbà kiniun, ti nrìn, ati ọmọ kiniun, kò si si ẹniti o dẹruba wọn? Kiniun ti fàya pẹrẹpẹrẹ tẹrùn fun awọn ọmọ rẹ̀, o si fun li ọrun pa fun awọn abo kiniun rẹ̀, o si fi ohun ọdẹ kún isà rẹ̀, ati ihò rẹ̀ fun onjẹ agbara. Kiyesi i, emi dojukọ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, emi o si fi kẹkẹ́ rẹ̀ wọnni joná ninu ẹ̃fin, idà yio si jẹ ọmọ kiniun rẹ wọnni run: emi o si ke ohun ọdẹ rẹ kuro lori ilẹ aiye, ohùn awọn ojiṣẹ rẹ li a kì yio si tún gbọ́ mọ.

Nah 2:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe. Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò; máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ, kí o sì múra ogun. (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada bí ògo Israẹli, nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn, wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.) Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀, ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀ Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànà bí ọwọ́ iná; nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ, àwọn ẹṣin wọn ń yan. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo, wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede; wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù, wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná. Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ, wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n yára lọ sí ibi odi, wọ́n sì fi asà dira ogun. Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀, ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin. A tú ayaba sí ìhòòhò, a sì mú un lọ sí ìgbèkùn, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí, wọ́n ń rin bí oriri. Ìlú Ninefe dàbí adágún odò tí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ. Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!” Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada. Ẹ kó fadaka, ẹ kó wúrà! Ìlú náà kún fún ìṣúra, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye. A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro! Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú, orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ìrora dé bá ọpọlọpọ, gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì. Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà? Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun? Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà, tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú? Akọ kinniun a máa fa ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀, a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀; a máa kó ẹran tí ó bá pa ati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”

Nah 2:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le, múra gírí. OLúWA yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́. Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná. Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀. A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀. A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà, wọn a sì máa lu àyà wọn. Ninefe dàbí adágún omi, tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn. “Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!” Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀, Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀ àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ. “Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”