Mak 6:1-29
Mak 6:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI jade nibẹ̀, o wá si ilu on tikararẹ̀; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? Gbẹnagbẹna na kọ yi, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Jose, ati ti Juda, ati Simoni? awọn arabinrin rẹ̀ kò ha si wà nihinyi lọdọ wa? Nwọn si kọsẹ̀ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀. On ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ̀, jù pe o gbé ọwọ́ rẹ̀ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada. Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni. O si pè awọn mejila na sọdọ rẹ̀, o bẹ̀rẹ si irán wọn lọ ni meji-meji; o si fi aṣẹ fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́; O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe mu ohunkohun, lọ si àjo wọn, bikoṣe ọpá nikan; ki nwọn ki o máṣe mu àpo, tabi akara, tabi owo ninu asuwọn wọn: Ṣugbọn ki nwọn ki o wọ̀ salubàta: ki nwọn máṣe wọ̀ ẹ̀wu meji. O si wi fun wọn pe, Nibikibi ti ẹnyin ba wọ̀ ile kan, nibẹ̀ ni ki ẹ mã gbé titi ẹnyin o fi jade kuro nibẹ̀ na. Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọrọ̀ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro nibẹ̀, ẹ gbọ̀n eruku ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu nla na lọ. Nwọn si jade lọ, nwọn si wasu ki awọn enia ki o le ronupiwada. Nwọn si lé ọ̀pọ awọn ẹmi èṣu jade, nwọn si fi oróro kùn ọ̀pọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, nwọn si mu wọn larada. Herodu ọba si gburo rẹ̀; (nitoriti okikí orukọ rẹ̀ kàn yiká:) o si wipe, Johanu Baptisti jinde kuro ninu oku, nitorina ni iṣẹ agbara ṣe nṣe lati ọwọ rẹ̀ wá. Awọn ẹlomiran wipe, Elijah ni. Ṣugbọn awọn miran wipe, Woli kan ni, tabi bi ọkan ninu awọn woli. Ṣugbọn nigbati Herodu gbọ́, o wipe, Johanu ni, ẹniti mo ti bẹ́ lori: on li o jinde kuro ninu okú. Herodu tikararẹ̀ sá ti ranṣẹ mu Johanu, o si dè e sinu tubu nitori Herodia, aya Filippi arakunrin rẹ̀: on sá ti fi i ṣe aya. Johanu sá ti wi fun Herodu pe, kò tọ́ fun iwọ lati ni aya arakunrin rẹ. Nitorina ni Herodia ṣe ni i sinu, on si nfẹ ipa a; ṣugbọn kò le ṣe e: Nitori Herodu bẹ̀ru Johanu, o si mọ̀ ọ li olõtọ enia ati ẹni mimọ́, o si ntọju rẹ̀; nigbati o gbọrọ rẹ̀, o ṣe ohun pipọ, o si fi ayọ̀ gbọrọ rẹ̀. Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili; Nigbati ọmọbinrin Herodia si wọle, ti o si njó, o mu inu Herodu dùn ati awọn ti o ba a joko, ọba si wi fun ọmọbinrin na pe, Bère ohunkohun ti iwọ fẹ lọwọ mi, emi o si fifun ọ. O si bura fun u, wipe, Ohunkohun ti iwọ ba bere lọwọ mi, emi o si fifun ọ, titi fi de idameji ijọba mi. O si jade lọ, o wi fun iya rẹ̀ pe, Kini ki emi ki o bère? On si wipe, Ori Johanu Baptisti. Lojukanna, o si wọle tọ̀ ọba wá kánkan, o bère, wipe, emi nfẹ ki iwọ ki o fi ori Johanu Baptisti fun mi ninu awopọkọ nisisiyi. Inu ọba si bajẹ gidigidi; ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati nitori awọn ti o bá a joko pọ̀, kò si fẹ ikọ̀ fun u. Lọgan ọba si rán ẹṣọ́ kan, o fi aṣẹ fun u pe, ki o gbé ori rẹ̀ wá: o si lọ, o bẹ́ Johanu lori ninu tubu. O si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, o si fi fun ọmọbinrin na: ọmọbinrin na si fi fun iya rẹ̀. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́, nwọn wá, nwọn gbé okú rẹ̀, nwọn si lọ tẹ́ ẹ sinu ibojì.
Mak 6:1-29 Yoruba Bible (YCE)
Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá a lọ. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé. Ẹnu ya ọpọlọpọ àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń wí pé, “Níbo ni eléyìí ti kọ́ ẹ̀kọ́? Irú ọgbọ́n wo ni ọgbọ́n tirẹ̀ yìí, tí iṣẹ́ ìyanu ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? Ṣebí gbẹ́nàgbẹ́nà ni, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Juda, ati Simoni? Ṣebí àwọn arabinrin rẹ̀ nìwọ̀nyí lọ́dọ̀ wa yìí?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì, àfi ní ìlú ara rẹ̀, ati láàrin àwọn ará rẹ̀, ati ninu ẹbí rẹ̀.” Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀ àfi pé ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé àwọn aláìsàn bíi mélòó kan, a sì wò wọ́n sàn. Ẹnu yà á nítorí aigbagbọ wọn. Jesu ń káàkiri gbogbo àwọn abúlé tí ó wà yíká, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má mú ohunkohun lọ́wọ́ ní ọ̀nà àjò náà àfi ọ̀pá nìkan. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, tabi igbá báárà lọ́wọ́, tabi kí wọn fi owó sinu àpò wọn. Kí wọn wọ bàtà, ṣugbọn kí wọn má wọ ẹ̀wù meji. Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti kìlọ̀ fún wọn.” Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada. Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá. Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń wí pé, “Elija ni.” Àwọnmìíràn ní, “Wolii ni, bí ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́.” Ṣugbọn nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ó ní, “Johanu tí mo ti bẹ́ lórí ni ó jí dìde.” Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà. Nítorí Johanu a máa wí fún Hẹrọdu pé, “Kò yẹ fún ọ láti gba iyawo arakunrin rẹ.” Nítorí náà Hẹrọdiasi ní Johanu sinu, ó fẹ́ pa á, ṣugbọn kò lè pa á, nítorí Hẹrọdu bẹ̀rù Johanu, nítorí ó mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni ati pé kò ní àléébù. Nítorí náà ó dáàbò bò ó. Ọkàn Hẹrọdu a máa dàrú gidigidi nígbàkúùgbà tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, sibẹ a máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili. Ọmọ Hẹrọdiasi obinrin bá wọlé, ó bọ́ sí agbo, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó, inú Hẹrọdu ati ti àwọn tí ó wà níbi àsè náà dùn. Ọba sọ fún ọmọbinrin náà pé, “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́, n óo fi í fún ọ.” Ó bá búra fún un pé, “N óo fún ọ ní ohunkohun tí o bá bèèrè, kì báà ṣe ìdajì ìjọba mi.” Ọmọbinrin náà bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó ní, “Kí ni kí n bèèrè?” Ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Bèèrè orí Johanu Onítẹ̀bọmi.” Ọmọbinrin náà yára lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó wí pé, “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Johanu Onítẹ̀bọmi kíákíá, kí wọ́n fi àwo pẹrẹsẹ gbé e wá.” Inú ọba bàjẹ́ pupọ, ṣugbọn nítorí ó ti ṣe ìlérí pẹlu ìbúra lójú àwọn tí ó wà níbi àsè, kò fẹ́ kọ̀ fún un. Lẹsẹkẹsẹ ọba rán ọmọ-ogun kan, ó pàṣẹ fún un kí ó gbé orí Johanu wá. Ó bá lọ, ó bẹ́ ẹ lórí ninu ilé ẹ̀wọ̀n. Ó bá fi àwo pẹrẹsẹ gbé orí rẹ̀ wá, ó fi í fún ọmọbinrin náà. Ọmọbinrin náà bá gbé e lọ fún ìyá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sin ín sinu ibojì.
Mak 6:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí Sinagọgu láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì ya àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́. Wọ́n wí pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, tí irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? Gbẹ́nàgbẹ́nà náà kọ́ yìí? Ọmọ Maria àti arákùnrin Jakọbu àti Josẹfu, Judasi àti Simoni? Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀. Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrín àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.” Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrín wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn. Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jesu lọ sí àárín àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn. Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́. O sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò ìgbànú, tàbí owó lọ́wọ́. Wọn kò tilẹ̀ gbọdọ̀ mú ìpààrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́. Jesu wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe sípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.” Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn. Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá. Láìpẹ́, ọba Herodu gbọ́ nípa Jesu, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi jíǹde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ.” Àwọn mìíràn wí pé, “Elijah ní.” Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Herodu gbọ́ èyí, ó wí pé “Johanu tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.” Herodu fúnrarẹ̀ sá ti ránṣẹ́ mú Johanu, tìkára rẹ̀ sínú túbú nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya. Johanu sì ti wí fún Herodu pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.” Nítorí náà ni Herodia ṣe ní sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le ṣe é. Nítorí Herodu bẹ̀rù Johanu, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòtítọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Herodu ba gbọ́rọ̀ Johanu, ó máa ń dààmú síbẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀. Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili. Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.” Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.” Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé “Kí ní kí ń béèrè?” Ó dáhùn pé, “Orí Johanu Onítẹ̀bọmi.” Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.” Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìbúra rẹ, àti nítorí àwọn tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un. Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Johanu wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Johanu lórí nínú túbú. Ó sì gbé orí Johanu wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.