Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá a lọ. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé. Ẹnu ya ọpọlọpọ àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń wí pé, “Níbo ni eléyìí ti kọ́ ẹ̀kọ́? Irú ọgbọ́n wo ni ọgbọ́n tirẹ̀ yìí, tí iṣẹ́ ìyanu ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? Ṣebí gbẹ́nàgbẹ́nà ni, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Juda, ati Simoni? Ṣebí àwọn arabinrin rẹ̀ nìwọ̀nyí lọ́dọ̀ wa yìí?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́.
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì, àfi ní ìlú ara rẹ̀, ati láàrin àwọn ará rẹ̀, ati ninu ẹbí rẹ̀.”
Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀ àfi pé ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé àwọn aláìsàn bíi mélòó kan, a sì wò wọ́n sàn. Ẹnu yà á nítorí aigbagbọ wọn.
Jesu ń káàkiri gbogbo àwọn abúlé tí ó wà yíká, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má mú ohunkohun lọ́wọ́ ní ọ̀nà àjò náà àfi ọ̀pá nìkan. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, tabi igbá báárà lọ́wọ́, tabi kí wọn fi owó sinu àpò wọn. Kí wọn wọ bàtà, ṣugbọn kí wọn má wọ ẹ̀wù meji. Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti kìlọ̀ fún wọn.”
Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada. Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá.
Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.”
Ṣugbọn àwọn mìíràn ń wí pé, “Elija ni.”
Àwọnmìíràn ní, “Wolii ni, bí ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́.”
Ṣugbọn nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ó ní, “Johanu tí mo ti bẹ́ lórí ni ó jí dìde.” Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà. Nítorí Johanu a máa wí fún Hẹrọdu pé, “Kò yẹ fún ọ láti gba iyawo arakunrin rẹ.”
Nítorí náà Hẹrọdiasi ní Johanu sinu, ó fẹ́ pa á, ṣugbọn kò lè pa á, nítorí Hẹrọdu bẹ̀rù Johanu, nítorí ó mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni ati pé kò ní àléébù. Nítorí náà ó dáàbò bò ó. Ọkàn Hẹrọdu a máa dàrú gidigidi nígbàkúùgbà tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, sibẹ a máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili. Ọmọ Hẹrọdiasi obinrin bá wọlé, ó bọ́ sí agbo, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó, inú Hẹrọdu ati ti àwọn tí ó wà níbi àsè náà dùn. Ọba sọ fún ọmọbinrin náà pé, “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́, n óo fi í fún ọ.” Ó bá búra fún un pé, “N óo fún ọ ní ohunkohun tí o bá bèèrè, kì báà ṣe ìdajì ìjọba mi.”
Ọmọbinrin náà bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó ní, “Kí ni kí n bèèrè?”
Ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Bèèrè orí Johanu Onítẹ̀bọmi.”
Ọmọbinrin náà yára lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó wí pé, “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Johanu Onítẹ̀bọmi kíákíá, kí wọ́n fi àwo pẹrẹsẹ gbé e wá.”
Inú ọba bàjẹ́ pupọ, ṣugbọn nítorí ó ti ṣe ìlérí pẹlu ìbúra lójú àwọn tí ó wà níbi àsè, kò fẹ́ kọ̀ fún un. Lẹsẹkẹsẹ ọba rán ọmọ-ogun kan, ó pàṣẹ fún un kí ó gbé orí Johanu wá. Ó bá lọ, ó bẹ́ ẹ lórí ninu ilé ẹ̀wọ̀n. Ó bá fi àwo pẹrẹsẹ gbé orí rẹ̀ wá, ó fi í fún ọmọbinrin náà. Ọmọbinrin náà bá gbé e lọ fún ìyá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sin ín sinu ibojì.