Mak 15:42-47
Mak 15:42-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati alẹ si lẹ, nitoriti iṣe ọjọ ipalẹmọ, eyini ni, ọjọ ti o ṣiwaju ọjọ isimi, Josefu ara Arimatea, ọlọlá ìgbimọ, ẹniti on tikalarẹ̀ pẹlu nreti ijọba Ọlọrun, o wá, o si wọle tọ̀ Pilatu lọ laifòya, o si tọrọ okú Jesu. Ẹnu si yà Pilatu gidigidi, bi o ti kú na: o si pè balogun ọrún, o bi i lẽre bi igba ti o ti kú ti pẹ diẹ. Nigbati o si mọ̀ lati ọdọ balọgun ọrún na, o si fi okú na fun Josefu. O si rà aṣọ ọgbọ wá, o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ ọgbọ na dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu apata, o si yi okuta kan di ẹnu-ọ̀na ibojì na. Ati Maria Magdalene, ati Maria iya Jose, ri ibi ti a gbé tẹ́ ẹ si.
Mak 15:42-47 Yoruba Bible (YCE)
Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu. Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. Maria Magidaleni ati Maria ìyá Josẹfu ń wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.
Mak 15:42-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú, Josẹfu ará Arimatea wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pilatu láti tọrọ òkú Jesu. Ẹnu ya Pilatu láti gbọ́ pé Jesu ti kú. Nítorí náà ó pe balógun ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jesu ti kú nítòótọ́. Nígbà tí balógun ọ̀rún náà sì fún Pilatu ni ìdánilójú pé Jesu ti kú, Pilatu jọ̀wọ́ òkú rẹ̀ fún Josẹfu. Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.