Mak 15:37-39
Mak 15:37-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́. Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”
Mak 15:37-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ. Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ. Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe.
Mak 15:37-39 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili bá ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”