Mak 15:25-32
Mak 15:25-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu. A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU. Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.
Mak 15:25-32 Yoruba Bible (YCE)
Ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Àkọlé orí agbelebu tí wọ́n kọ, tí ó jẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni: “Ọba àwọn Juu.” Ní àkókò kan náà, wọ́n kan àwọn ọlọ́ṣà meji kan mọ́ agbelebu, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ọwọ́ òsì rẹ̀. [ Báyìí ni àkọsílẹ̀ kan ṣẹ tí ó wí pé, “A kà á kún àwọn arúfin.”] Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.” Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú.
Mak 15:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni: ọba àwọn júù. Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.