Mak 15:20-39

Mak 15:20-39 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú. Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu. A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU. Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀. Nigbati o di wakati kẹfa, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Ni wakati kẹsan ni Jesu si kigbe soke li ohùn rara, wipe, Eloi, Eloi, lama sabaktani? itumọ eyi ti ijẹ, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, Wò o, o npè Elijah. Ẹnikan si sare, o fi sponge bọ ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o fifun u mu, wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẹ jẹ ki a ma wò bi Elijah yio wá gbé e sọkalẹ. Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ. Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ. Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe.

Mak 15:20-39 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí wọ́n ti fi ṣe ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì kúrò ní ara rẹ̀, wọ́n fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n bá fà á jáde láti lọ kàn án mọ́ agbelebu. Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu. Wọ́n wá mú Jesu lọ sí ibìkan tí à ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”). Wọ́n fún un ní ọtí tí wọ́n ti po òjíá mọ́, ṣugbọn kò gbà á. Wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí aṣọ rẹ̀ láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́. Ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Àkọlé orí agbelebu tí wọ́n kọ, tí ó jẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni: “Ọba àwọn Juu.” Ní àkókò kan náà, wọ́n kan àwọn ọlọ́ṣà meji kan mọ́ agbelebu, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ọwọ́ òsì rẹ̀. [ Báyìí ni àkọsílẹ̀ kan ṣẹ tí ó wí pé, “A kà á kún àwọn arúfin.”] Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.” Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀, títí di agogo mẹta ọ̀sán. Nígbà tí ó di agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe tòò, ó ní, “Eloi, Eloi, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Nígbà tí àwọn kan ninu àwọn tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ń wí pé, “Ẹ gbọ́! Ó ń pe Elija!” Ẹnìkan bá sáré, ó ti kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sí orí ọ̀pá láti fún un mu, ó ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á máa wò ó bí Elija yóo wá gbé e sọ̀kalẹ̀!” Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili bá ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”

Mak 15:20-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elése àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá, pé kí ó rú àgbélébùú Jesu. Wọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta, (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí) Wọ́n sì fi (myrri) wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á. Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù. Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni: ọba àwọn júù. Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀. Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”). Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.” Nígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.” Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́. Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa