Mak 15:1-5
Mak 15:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ATI lojukanna li owurọ, awọn olori alufa jọ gbìmọ pẹlu awọn alàgba, ati awọn akọwe, ati gbogbo ajọ ìgbimọ, nwọn si dè Jesu, nwọn si mu u lọ, nwọn si fi i le Pilatu lọwọ. Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i. Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan. Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ. Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu.
Mak 15:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́. Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Àwọn olórí alufaa ń fi ẹ̀sùn pupọ kàn án. Pilatu bá tún bi í pé, “O kò sì fèsì rárá? Ìwọ kò gbọ́ bí wọ́n ti ń fi oríṣìíríṣìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ni?” Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu.
Mak 15:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbàgbà, àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe. Wọ́n sì de Jesu, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pilatu lọ́wọ́. Pilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu sì dáhùn pé, “gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.” Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án. Pilatu sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.” Ṣùgbọ́n Jesu kò dalóhùn síbẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pilatu.