Mak 12:38-44
Mak 12:38-44 Yoruba Bible (YCE)
Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn ipò ọlá nínú sinagọgu ati ní ibi àsè. Wọ́n a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gbadura gígùn nítorí àṣehàn. Ìdájọ́ tí wọn yóo gbà yóo le pupọ.” Bí Jesu ti jókòó lọ́kàn-ánkán àpótí owó, ó ń wò bí ọpọlọpọ eniyan ti ń dá owó sinu àpótí. Ọpọlọpọ àwọn ọlọ́rọ̀ ń dá owó pupọ sinu àpótí owó. Nígbà náà ni talaka opó kan wá, ó dá eépìnnì meji tí ó jẹ́ kọbọ kan sinu àpótí. Jesu wá tọ́ka sí èyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Mo ń wí fun yín gbangba pé opó talaka yìí dá owó ju gbogbo àwọn tí ó dá owó sinu àpótí lọ. Nítorí ninu ọpọlọpọ ọrọ̀ ni àwọn yòókù ti mú ohun tí wọ́n dá, ṣugbọn òun, ninu àìní rẹ̀, ó dá gbogbo ohun tí ó ní, àní gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀.”
Mak 12:38-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.” Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”
Mak 12:38-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikíni li ọjà, Ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi ase; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gigun fun aṣehàn: awọn wọnyi ni yio jẹbi pọ̀ju. Jesu si joko kọjusi apoti iṣura, o si nwò bi ijọ enia ti nsọ owo sinu apoti iṣura: ọ̀pọ awọn ọlọrọ̀ si sọ pipọ si i. Talakà opó kan si wá, o sọ owo idẹ wẹ́wẹ meji ti iṣe idameji owo-bàba kan sinu rẹ̀. O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Talakà opó yi sọ sinu apoti iṣura jù gbogbo awọn ti o sọ sinu rẹ̀ lọ. Nitori gbogbo nwọn sọ sinu rẹ̀ ninu ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rẹ̀ o sọ ohun gbogbo ti o ni si i, ani gbogbo ini rẹ̀.