Mak 12:28-34
Mak 12:28-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin? Jesu si da a lohùn, wipe, Ekini ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: eyi li ofin ekini. Ekeji si dabi rẹ̀, Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ko si si ofin miran, ti o tobi jù wọnyi lọ. Akọwe na si wi fun u pe, Olukọni, o dara, otitọ li o sọ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; ko si si omiran bikoṣe on: Ati ki a fi gbogbo àiya, ati gbogbo òye, ati gbogbo ọkàn, ati gbogbo agbara fẹ ẹ, ati ki a fẹ ọmọnikeji ẹni bi ara-ẹni, o jù gbogbo ẹbọ-sisun ati ẹbọ lọ. Nigbati Jesu ri i pe o fi òye dahùn, o wi fun u pe, Iwọ kò jìna si ijọba Ọlọrun. Lẹhin eyini, kò si ẹnikan ti o jẹ bi i lẽre ohunkan mọ́.
Mak 12:28-34 Yoruba Bible (YCE)
Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?” Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa. Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’ Èyí tí ó ṣìkejì ni pé, ‘Kí ìwọ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tí ó tóbi ju èyí lọ.” Amòfin náà wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Olùkọ́ni. Òtítọ́ ni o sọ pé, ‘Ọlọrun kan ni ó wà. Kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀’; ati pé, ‘Kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa bí a ti fẹ́ràn ara wa’ tayọ gbogbo ẹbọ sísun ati ẹbọ yòókù.” Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.” Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.
Mak 12:28-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?” Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.” Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan. Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.” Jesu rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jesu sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu.