Mak 12:24-30
Mak 12:24-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ki ha ṣe nitori eyi li ẹ ṣe ṣina, pe ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ, tabi agbara Ọlọrun? Nitori nigbati nwọn o jinde kuro ninu okú, nwọn kò ni gbeyawo, bẹ̃ni nwọn kì yio sinni ni iyawo; ṣugbọn nwọn ó dabi awọn angẹli ti mbẹ li ọrun. Ati niti awọn okú pe a o ji wọn dide: ẹnyin ko ti kà a ninu iwe Mose, bi Ọlọrun ti sọ fun u ninu igbẹ́, wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? On kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe Ọlọrun awọn alãye: nitorina ẹnyin ṣìna gidigidi. Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin? Jesu si da a lohùn, wipe, Ekini ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: eyi li ofin ekini.
Mak 12:24-30 Yoruba Bible (YCE)
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun? Nítorí nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò sí pé à ń gbé iyawo tabi à ń fa obinrin fún ọkọ, ṣugbọn bí àwọn angẹli ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’ Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.” Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?” Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa. Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’
Mak 12:24-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.” Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?” Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’