Mak 12:1-27
Mak 12:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si bẹ̀rẹ si ifi owe ba wọn sọ̀rọ pe, Ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si ṣọgba yi i ká, o si wà ibi ifunti waini, o si kọ́ ile-isọ si i, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si àjo. Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn oluṣọgba na, ki o le gbà ninu eso ọgba ajara na lọwọ awọn oluṣọgba. Nwọn si mu u, nwọn lù u, nwọn si rán a pada lọwọ̀ ofo. O si tún rán ọmọ-ọdọ miran si wọn, on ni nwọn si sọ okuta lù, nwọn sá a logbẹ́ li ori, nwọn si ran a lọ ni itiju. O si tún rán omiran; eyini ni nwọn si pa: ati ọ̀pọ miran, nwọn lù miran, nwọn si pa miran. Ṣugbọn o kù ọmọ rẹ̀ kan ti o ni, ti iṣe ayanfẹ rẹ̀, o si rán a si wọn pẹlu nikẹhin, o wipe, Nwọn ó ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. Ṣugbọn awọn oluṣọgba wọnni wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ogún rẹ̀ yio si jẹ tiwa. Nwọn si mu u, nwọn pa a, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu ọgba ajara na. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe? On o wá, yio si pa awọn oluṣọgba wọnni run, yio si fi ọgba ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn ẹlomiran. Ẹnyin kò ha ti kà iwe-mimọ yi; Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ on na li o di pàtaki igun ile: Eyi ni ìṣe Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? Nwọn si nwá ọ̀na ati mu u, sugbọn nwọn si bẹ̀ru ijọ enia: nitori nwọn mọ̀ pe, awọn li o powe na mọ: nwọn si fi i silẹ, nwọn lọ. Nwọn si rán awọn kan si i ninu awọn Farisi, ati ninu awọn ọmọ-ẹhin Herodu, lati fi ọ̀rọ rẹ̀ mu u. Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u? Ṣugbọn Jesu mọ̀ agabagebe wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? ẹ mu owo-idẹ kan fun mi wá ki emi ki o wò o. Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi. Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀. Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ. Eyi ekeji si ṣu u lopó, on si kú, bẹ̃li on kò si fi ọmọ silẹ: gẹgẹ bẹ̃ si li ẹkẹta. Awọn mejeje si ṣu u lopó, nwọn kò si fi ọmọ silẹ: nikẹhin gbogbo wọn obinrin na kú pẹlu. Njẹ li ajinde, nigbati nwọn ba jinde, aya tani yio ha ṣe ninu wọn? awọn mejeje li o sá ni i li aya? Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ki ha ṣe nitori eyi li ẹ ṣe ṣina, pe ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ, tabi agbara Ọlọrun? Nitori nigbati nwọn o jinde kuro ninu okú, nwọn kò ni gbeyawo, bẹ̃ni nwọn kì yio sinni ni iyawo; ṣugbọn nwọn ó dabi awọn angẹli ti mbẹ li ọrun. Ati niti awọn okú pe a o ji wọn dide: ẹnyin ko ti kà a ninu iwe Mose, bi Ọlọrun ti sọ fun u ninu igbẹ́, wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? On kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe Ọlọrun awọn alãye: nitorina ẹnyin ṣìna gidigidi.
Mak 12:1-27 Yoruba Bible (YCE)
Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn. Ṣugbọn nínà ni wọ́n nà án, wọ́n bá lé e pada ní ọwọ́ òfo. Ó tún rán ẹrú mìíràn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n lu òun lórí ní àlùbẹ́jẹ̀, wọ́n sì dójú tì í. Nígbà tí ó rán ẹrú mìíràn lọ, pípa ni wọ́n pa á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọpọlọpọ àwọn ẹrú mìíràn, wọ́n lu àwọn kan, wọ́n pa àwọn mìíràn. Ó wá ku ẹnìkan tíí ṣe àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni ó rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọn yóo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn àwọn alágbàro náà wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ jẹ́ tiwa.’ Nígbà náà ni wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n bá wọ́ ọ jù sẹ́yìn ọgbà àjàrà. “Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóo ṣe? Yóo wá, yóo pa àwọn alágbàro wọ̀n-ọn-nì, yóo sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàro mìíràn. Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́, pé, ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ ni ó di pataki igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, Ìyanu ni ó jẹ́ ní ojú wa.’ ” Àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin ati àwọn àgbà ń wá ọ̀nà láti mú un, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ. Wọ́n rán àwọn kan ninu àwọn Farisi ati àwọn ọ̀rẹ́ Hẹrọdu sí i láti lọ gbọ́ tẹnu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, sọ fún wa, ṣé ó tọ̀nà pé kí á máa san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?” Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadaka kan wá fún mi kí n rí i.” Wọ́n fún un ní ọ̀kan. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ó wà ní ara rẹ̀ yìí?” Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi nǹkan tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Ọlọrun, ẹ fi fún Ọlọrun.” Ẹnu yà wọ́n pupọ sí ìdáhùn rẹ̀. Ní àkókò náà, àwọn Sadusi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n ní kò sí ohun tí ń jẹ́ ajinde òkú.) Wọ́n ní, “Olùkọ́ni, Mose kọ òfin kan fún wa pé bí ọkunrin kan bá kú, tí ó fi aya sílẹ̀, tí kò bá ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó kí ó lè ní ọmọ ní orúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà, èyí ekinni fẹ́ aya, ó kú láì ní ọmọ, Ekeji ṣú aya rẹ̀ lópó, ṣugbọn òun náà kú láì ní ọmọ. Ẹkẹta náà kú láì ní ọmọ. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣá ṣe kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo wọn, obinrin náà kú. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ ajinde, iyawo ta ni obinrin yìí yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ni ó ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun? Nítorí nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò sí pé à ń gbé iyawo tabi à ń fa obinrin fún ọkọ, ṣugbọn bí àwọn angẹli ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’ Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.”
Mak 12:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà. Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn. “Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’ “Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà. “Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀ òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé. Èyí ni iṣẹ́ Olúwa ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?” Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisi pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú. Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un? Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀. Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, “Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?” Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”