Mak 11:1-11

Mak 11:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI nwọn si sunmọ eti Jerusalemu, leti Betfage ati Betani, li òke Olifi, o rán meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin: lojukanna bi ẹnyin ti nwọ̀ inu rẹ̀ lọ, ẹnyin ó si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn rì; ẹ tú u, ki é si fà a wá. Bi ẹnikẹni ba si wi fun nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi? ẹ wipe, Oluwa ni fi ṣe; lojukanna yio si rán a wá sihinyi. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ na ti a so li ẹnu-ọ̀na lode ni ita gbangba; nwọn si tú u. Awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe, ti ẹnyin fi ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ nì? Nwọn si wi fun wọn gẹgẹ bi Jesu ti wi fun wọn: nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. Nwọn si fà ọmọ kẹtẹkẹtẹ na tọ̀ Jesu wá, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin rẹ̀; on si joko lori rẹ̀. Awọn pipọ si tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na: ati awọn miran ṣẹ́ ẹ̀ka igi, nwọn si fún wọn si ọ̀na. Ati awọn ti nlọ niwaju, ati awọn ti mbọ̀ lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna; Olubukun li ẹniti o mbọ̀wá li orukọ Oluwa: Olubukun ni ijọba ti mbọ̀wá, ijọba Dafidi, baba wa: Hosanna loke ọrun. Jesu si wọ̀ Jerusalemu, ati tẹmpili. Nigbati o si wò ohun gbogbo yiká, alẹ sa ti lẹ tan, o si jade lọ si Betani pẹlu awọn mejila.

Mak 11:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, nítòsí Bẹtifage ati Bẹtani, ní orí Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ẹ̀ ń wò ní ọ̀kánkán yìí, bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, tí wọ́n so mọ́ èèkàn, ẹ tú u, kí ẹ fà á wá. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú u?’ Kí ẹ dáhùn pé, ‘Oluwa fẹ́ lò ó ni, lẹsẹkẹsẹ tí ó bá ti lò ó tán yóo dá a pada sibẹ.’ ” Wọ́n lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu ìlẹ̀kùn lóde, lẹ́bàá títì, wọ́n bá tú u. Àwọn kan tí wọ́n ti jókòó níbẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?” Wọ́n bá dá wọn lóhùn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí fún wọn. Àwọn eniyan náà sì yọ̀ǹda fún wọn. Wọ́n bá fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí orí rẹ̀, Jesu bá gùn un. Ọpọlọpọ eniyan tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà, àwọn mìíràn tẹ́ ẹ̀ka igi tí wọ́n ya ní pápá. Àwọn tí ó ń lọ ní iwájú ati àwọn tí ó ń bọ̀ ní ẹ̀yìn ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa. Ibukun ni ìjọba tí ń bọ̀, ìjọba Dafidi baba ńlá wa. Hosana ní òkè ọ̀run!” Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

Mak 11:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá sí ibi yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u. Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?” Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ. Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀. Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà. Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!” “Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!” “Hosana lókè ọ̀run!” Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa