Marku 11:1-11

Marku 11:1-11 YCB

Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá sí ibi yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u. Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?” Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ. Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀. Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà. Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!” “Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!” “Hosana lókè ọ̀run!” Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.