Mik 5:2-5
Mik 5:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye. Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli. On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye. Eleyi ni yio jẹ alafia, nigbati ara Assiria yio wá si ilẹ wa; nigbati yio si tẹ̀ awọn ãfin wa mọlẹ, nigba nã li awa o gbe oluṣọ agutan meje dide si i, ati olori enia mẹjọ.
Mik 5:2-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.” Nítorí náà, OLUWA yóo kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ títí tí ẹni tí ń rọbí yóo fi bímọ; nígbà náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù yóo pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Yóo dìde, yóo sì mójútó àwọn eniyan rẹ̀ pẹlu agbára OLUWA, àní, ninu ọláńlá orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Wọn óo máa gbé ní àìléwu, nítorí yóo di ẹni ńlá jákèjádò gbogbo ayé. Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia.
Mik 5:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata, bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.” Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli. Òun yóò sì dúró, yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára OLúWA, ní ọláńlá orúkọ OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Wọn yóò sì wà láìléwu, nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ yóò sì dé òpin ayé. Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn. Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa, nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i, àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.