Mika 5

5
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà láti Bẹtilẹhẹmu
1Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,
ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,
nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.
Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
2“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,
bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,
nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli
yóò ti jáde tọ̀ mí wá,
ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà láéláé.”
3Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá
títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,
àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà
láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.
4Òun yóò sì dúró,
yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa,
ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
Wọn yóò sì wà láìléwu,
nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ
yóò sì dé òpin ayé.
Ìgbàlà àti ìparun
5Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn.
Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa
tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa,
nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i,
àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.
6Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run,
àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà.
Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asiria
nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa
tí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa.
7Ìyókù Jakọbu yóò sì wà
láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn
bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa,
bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko,
tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn
tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.
8Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà
ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn,
bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó,
bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn,
èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,
tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.
9A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun.
10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ
èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
11Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run,
èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.
12Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,
ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.
13Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run,
àti ọwọ́n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀;
ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀
fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.
14Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀,
èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.
15Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú
lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mika 5: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀