Mik 5:1-15

Mik 5:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

NISISIYI gbá ara rẹ jọ li ọwọ́, Iwọ ọmọbinrin ọwọ́: o ti dó tì wa; nwọn o fi ọ̀pa lu onidajọ Israeli li ẹ̀rẹkẹ. Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye. Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli. On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye. Eleyi ni yio jẹ alafia, nigbati ara Assiria yio wá si ilẹ wa; nigbati yio si tẹ̀ awọn ãfin wa mọlẹ, nigba nã li awa o gbe oluṣọ agutan meje dide si i, ati olori enia mẹjọ. Nwọn o si fi idà pa ilẹ Assiria run, ati ilẹ Nimrodu ni àbawọ̀ inu rẹ̀: yio si gbà wa lọwọ ara Assiria nigbati o ba wá ilẹ wa, ati nigbati o ba si ntẹ̀ àgbegbe wa mọlẹ. Iyokù Jakobu yio si wà lãrin ọ̀pọ enia bi irì lati ọdọ Oluwa wá, bi ọwarà òjo lori koriko, ti kì idara duro de enia, ti kì isi duro de awọn ọmọ enia. Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà. A o gbe ọwọ́ rẹ soke sori awọn ọ̀ta rẹ, gbogbo awọn ọ̀ta rẹ, li a o si ke kuro. Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa wi, ti emi o ke awọn ẹṣin rẹ kuro lãrin rẹ, emi o si pa awọn kẹkẹ́ ogun rẹ run. Emi o si ke ilu-nla ilẹ rẹ kuro, emi o si tì gbogbo odi rẹ ṣubu: Emi o si ke iwà-ajẹ kuro lọwọ rẹ: iwọ kì yio si ni alafọ̀ṣẹ mọ: Ere fifin rẹ pẹlu li emi o ke kuro, awọn ere rẹ kuro lãrin rẹ; iwọ kì o si ma sin iṣẹ ọwọ́ rẹ mọ. Emi o si tú igbo òriṣa rẹ kuro lãrin rẹ: emi o si pa awọn ilu rẹ run. Emi o si gbẹsan ni ibinu ati irunu lara awọn keferi, ti nwọn kò ti igbọ́ ri.

Mik 5:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Nisinsinyii, a ti fi odi yi yín ká, ogun sì ti dótì wá; wọ́n fi ọ̀pá na olórí Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.” Nítorí náà, OLUWA yóo kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ títí tí ẹni tí ń rọbí yóo fi bímọ; nígbà náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù yóo pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Yóo dìde, yóo sì mójútó àwọn eniyan rẹ̀ pẹlu agbára OLUWA, àní, ninu ọláńlá orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Wọn óo máa gbé ní àìléwu, nítorí yóo di ẹni ńlá jákèjádò gbogbo ayé. Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia. Nígbà tí àwọn ará Asiria bá wá gbógun tì wá, tí wọ́n bá sì wọ inú ilẹ̀ wa, a óo rán àwọn olórí wa ati àwọn akikanju láàrin wa láti bá wọn jà. Idà ni wọn yóo fi máa ṣe àkóso ilẹ̀ Asiria ati ilẹ̀ Nimrodu; wọn yóo sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Asiria, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ilẹ̀ wa tí wọ́n sì gbógun tì wá. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ati bí ọ̀wààrà òjò lára koríko, tí kò ti ọwọ́ eniyan wá. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. O óo lágbára ju àwọn ọ̀tá rẹ lọ, a óo sì pa wọ́n run. Ní ọjọ́ náà, n óo pa àwọn ẹṣin yín run, n óo sì run gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun yín. N óo pa àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ yín run, n óo sì wó ibi ààbò yín lulẹ̀. N óo pa àwọn oṣó run ní ilẹ̀ yín, ẹ kò sì ní ní aláfọ̀ṣẹ kankan mọ́. N óo run àwọn ère ati àwọn òpó oriṣa yín, ẹ kò sì ní máa bọ iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́. N óo run àwọn ère oriṣa Aṣera láàrin yín, n óo sì run àwọn ìlú yín. Ninu ibinu ati ìrúnú mi, n óo gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò pa àṣẹ mi mọ́.

Mik 5:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. “Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata, bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.” Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli. Òun yóò sì dúró, yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára OLúWA, ní ọláńlá orúkọ OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Wọn yóò sì wà láìléwu, nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ yóò sì dé òpin ayé. Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn. Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa, nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i, àti olórí ènìyàn mẹ́jọ. Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run, àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà. Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asiria nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa. Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLúWA wa, bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn. Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là. A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun. “Ní ọjọ́ náà,” ni OLúWA wí, “Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run. Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run, èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya. Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́. Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run, àti ọwọ́n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀; ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́. Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀, èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run. Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”