Mik 4:1-5
Mik 4:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
YIO si ṣe li ọjọ ikẹhìn, a o fi oke ile Oluwa kalẹ lori awọn oke-nla, a o si gbe e ga jù awọn oke kekeke lọ; awọn enia yio si mã wọ́ sinu rẹ̀. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. Ṣugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan kì yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu Oluwa awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ. Nitori gbogbo awọn enia ni yio ma rìn, olukuluku li orukọ ọlọrun tirẹ̀, awa o si ma rìn li orukọ Oluwa Ọlọrun wa lai ati lailai.
Mik 4:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ, àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.” Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde, ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu. Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré; wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀, ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n; nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae.
Mik 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé OLúWA lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n, nítorí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ OLúWA. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.