Mik 4:1-13

Mik 4:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

YIO si ṣe li ọjọ ikẹhìn, a o fi oke ile Oluwa kalẹ lori awọn oke-nla, a o si gbe e ga jù awọn oke kekeke lọ; awọn enia yio si mã wọ́ sinu rẹ̀. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. Ṣugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan kì yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu Oluwa awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ. Nitori gbogbo awọn enia ni yio ma rìn, olukuluku li orukọ ọlọrun tirẹ̀, awa o si ma rìn li orukọ Oluwa Ọlọrun wa lai ati lailai. Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó amukun, emi o si ṣà ẹniti a le jade, ati ẹniti emi ti pọn loju jọ; Emi o si dá awọn amukun si fun iyokù, emi o si sọ ẹniti a ta nù rére di orilẹ-ède alagbara: Oluwa yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni lati isisiyi lọ, ati si i lailai. Ati iwọ, Ile iṣọ agbo agùtan, odi ọmọbinrin Sioni, si ọdọ rẹ ni yio wá, ani ijọba iṣãju; ijọba yio si wá si ọdọ ọmọbinrin Jerusalemu. Njẹ kini iwọ ha nkigbe soke si? ọba kò ha si ninu rẹ? awọn ìgbimọ rẹ ṣegbé bi? nitori irora ti dì ọ mu bi obinrin ti nrọbi. Ma rọbi, si bi, ọmọbinrin Sioni, bi ẹniti nrọbi: nitori nisisiyi ni iwọ o jade lọ kuro ninu ilu, iwọ o si ma gbe inu igbẹ́, iwọ o si lọ si Babiloni; nibẹ̀ ni a o gbà ọ; nibẹ̀ ni Oluwa yio rà ọ padà kuro lọwọ awọn ọta rẹ. Ati nisisiyi ọ̀pọlọpọ orile-ède gbá jọ si ọ, ti nwi pe, jẹ ki a sọ ọ di aimọ́, si jẹ ki oju wa ki o wo Sioni. Ṣugbọn nwọn kò mọ̀ erò Oluwa, bẹ̃ni oye ìmọ rẹ̀ kò ye wọn: nitori on o kó wọn jọ bi ití sinu ipaka. Dide, si ma pakà, Iwọ ọmọbinrin Sioni: nitori emi o sọ iwo rẹ di irin, emi o si sọ patakò rẹ di idẹ, iwọ o si run ọ̀pọlọpọ enia womu-womu: emi o si yá ère wọn sọtọ̀ fun Oluwa, ati iní wọn si Oluwa gbogbo aiye.

Mik 4:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ, àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.” Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde, ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu. Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré; wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀, ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n; nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae. OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú. N óo dá àwọn arọ sí, kí wọ́n lè wà lára àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n ṣẹ́kù, àwọn tí a túká yóo sì di orílẹ̀-èdè ńlá; OLUWA yóo sì jọba lórí wọn ní òkè Sioni láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.” Jerusalẹmu, ìwọ ilé ìṣọ́ agbo aguntan Sioni, ilé ọba rẹ àtijọ́ yóo pada sọ́dọ̀ rẹ, a óo dá ìjọba pada sí Jerusalẹmu. Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí? Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè dojú ìjà kọ yín nisinsinyii, wọ́n sì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sọ Sioni di aláìmọ́, kí á sì dójúlé e.” Ṣugbọn àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò mọ èrò OLUWA, ìpinnu rẹ̀ kò sì yé wọn, pé ó ti kó wọn jọ láti pa wọ́n bí ẹni pa ọkà ní ibi ìpakà. Ẹ dìde kí ẹ tẹ àwọn ọ̀tá yín mọ́lẹ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Nítorí n óo mú kí ìwo rẹ lágbára bí irin, pátákò ẹsẹ̀ rẹ yóo sì dàbí idẹ; o óo fọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè túútúú, o óo sì ya ọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún OLUWA, nǹkan ìní wọn yóo jẹ́ ti OLUWA àgbáyé.

Mik 4:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé OLúWA lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n, nítorí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ OLúWA. Ọlọ́run wa láé àti láéláé. OLúWA “Ní ọjọ́ náà,” ni OLúWA wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú. Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. OLúWA yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.” Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí. Máa yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Sioni, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Babeli; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni OLúWA yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!” Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú OLúWA; Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà. “Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún OLúWA àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.