Mat 26:1-13
Mat 26:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe, nigbati Jesu pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu. Nigbana li awọn olori alufa, awọn akọwe, ati awọn àgba awọn enia pejọ li ãfin olori alufa, ẹniti a npè ni Kaíafa, Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a. Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia. Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo? A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà. Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn ẹnyin kò ni mi nigbagbogbo. Nitori li eyi ti obinrin yi dà ororo ikunra yi si mi lara, o ṣe e fun sisinku mi. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a ba gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ pẹlu li a o si ròhin eyi ti obinrin yi ṣe, ni iranti rẹ̀.
Mat 26:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu parí gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn ọjọ́ meji ni Àjọ̀dún Ìrékọjá, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ láti kàn mọ́ agbelebu.” Nígbà náà ni àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú péjọ sí àgbàlá Olórí Alufaa tí ó ń jẹ́ Kayafa. Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á. Ṣugbọn wọ́n ń sọ pé, “Kí á má ṣe é ní àkókò àjọ̀dún, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìlú yóo dàrú.” Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí? Nítorí títà ni à bá ta òróró yìí ní owó iyebíye tí à bá fi fún àwọn talaka.” Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára. Nígbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, ṣugbọn ẹ kò ní máa rí mi láàrin yín nígbà gbogbo. Nítorí nígbà tí obinrin yìí da òróró yìí sí mi lára, ó ṣe é fún ìsìnkú mi ni. Mò ń sọ fun yín dájúdájú, níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé, a óo máa sọ nǹkan tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀.”
Mat 26:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.” Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa. Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á. Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.” Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀; Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.” Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo. Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìhìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”