Mat 26:1-13

Mat 26:1-13 YBCV

O SI ṣe, nigbati Jesu pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu. Nigbana li awọn olori alufa, awọn akọwe, ati awọn àgba awọn enia pejọ li ãfin olori alufa, ẹniti a npè ni Kaíafa, Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a. Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia. Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo? A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà. Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn ẹnyin kò ni mi nigbagbogbo. Nitori li eyi ti obinrin yi dà ororo ikunra yi si mi lara, o ṣe e fun sisinku mi. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a ba gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ pẹlu li a o si ròhin eyi ti obinrin yi ṣe, ni iranti rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ