Mat 25:1-13

Mat 25:1-13 Yoruba Bible (YCE)

“Ní àkókò náà, ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run yóo dàbí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wundia mẹ́wàá, tí wọn gbé àtùpà wọn láti jáde lọ pàdé ọkọ iyawo. Marun-un ninu wọn jẹ́ òmùgọ̀, marun-un sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Àwọn òmùgọ̀ gbé àtùpà, ṣugbọn wọn kò gbé epo lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́gbọ́n rọ epo sinu ìgò, wọ́n gbé e lọ́wọ́ pẹlu àtùpà wọn. Nígbà tí ọkọ iyawo pẹ́ kí ó tó dé, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé, wọ́n bá sùn lọ. “Nígbà tí ó di ààrin ọ̀gànjọ́, igbe ta pé, ‘Ọkọ iyawo dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’ Nígbà náà ni gbogbo àwọn wundia náà tají, wọ́n tún iná àtùpà wọn ṣe. Àwọn wundia òmùgọ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa ninu epo yín, nítorí àtùpà wa ń kú lọ.’ Àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Epo tí a ní kò tó fún àwa ati ẹ̀yin. Ẹ kúkú lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń ta epo, kí ẹ ra tiyín.’ Nígbà tí wọ́n lọ ra epo, ọkọ iyawo dé, àwọn tí wọ́n ti múra sílẹ̀ bá wọ ilé ibi igbeyawo pẹlu rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. “Ní ìgbẹ̀yìn àwọn wundia yòókù dé, wọ́n ní, ‘Alàgbà, alàgbà, ẹ ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé èmi kò mọ̀ yín.’ “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tabi àkókò.

Mat 25:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn. Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn. “Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’ “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe. Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí fìtílà wọn ń kú lọ. “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba à ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín. “Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àsè ìgbéyàwó, lẹ́yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. “Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’ “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’ “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ Ènìyàn yóò dé.