NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo.
Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn.
Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ:
Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu oróro ninu kolobo pẹlu fitila wọn.
Nigbati ọkọ iyawo pẹ, gbogbo wọn tõgbé, nwọn si sùn.
Ṣugbọn lãrin ọganjọ, igbe ta soke, wipe, Wo o, ọkọ, iyawo mbọ̀; ẹ jade lọ ipade rẹ̀.
Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe.
Awọn alaigbọn si wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu oróro nyin; nitori fitila wa nkú lọ.
Ṣugbọn awọn ọlọ́gbọn da wọn li ohùn, wipe, Bẹ̃kọ; ki o má ba ṣe alaito fun awa ati ẹnyin: ẹ kuku tọ̀ awọn ti ntà lọ, ki ẹ si rà fun ara nyin.
Nigbati nwọn si nlọ rà, ọkọ iyawo de; awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ si ibi iyawo: a si tì ilẹkun.
Ni ikẹhin li awọn wundia iyokù si de, nwọn nwipe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa.
Ṣugbọn o dahùn, wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin.
Nitorina, ẹ mã ṣọna, bi ẹnyin ko ti mọ̀ ọjọ, tabi wakati tí Ọmọ-enia yio de.