Mat 22:17-22
Mat 22:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? Ó tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́? Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe? Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ.
Mat 22:17-22 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?” Ṣugbọn Jesu mọ èrò ibi tí ó wà lọ́kàn wọn. Ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí ẹ̀yin alárèékérekè yìí? Ẹ fi owó tí ẹ fi ń san owó-orí hàn mí.” Wọ́n bá mú owó fadaka kan fún un. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
Mat 22:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?” Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.