Mat 22:1-10
Mat 22:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Jesu tún fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan, tí ó ń gbeyawo fún ọmọ rẹ̀. Ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ pe àwọn tí ó dájọ́ igbeyawo náà fún, ṣugbọn wọn kò fẹ́ wá. Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn, kí wọ́n sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Mo ti se àsè tán; mo ti pa mààlúù ati àwọn ẹran ọlọ́ràá; mo ti ṣe ètò gbogbo tán. Ẹ wá sí ibi igbeyawo.’ Ṣugbọn wọn kò bìkítà. Ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ sí ìdí òwò rẹ̀. Àwọn ìyókù ki àwọn ẹrú mọ́lẹ̀, wọ́n lù wọ́n pa. Inú wá bí ọba náà, ó bá rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ kí wọ́n pa àwọn apànìyàn wọ̀n-ọn-nì run, kí wọ́n sì dáná sun ìlú wọn. Ó bá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘A ti parí gbogbo ètò igbeyawo, ṣugbọn àwọn tí a ti pè kò yẹ. Ẹ wá lọ sí gbogbo oríta ìlú, ẹ pe gbogbo ẹni tí ẹ bá rí wá sí ibi igbeyawo.’ Àwọn ẹrú náà bá lọ sí ìgboro, wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí wá, ati àwọn eniyan rere, ati àwọn eniyan burúkú. Oniruuru eniyan bá kún ibi àsè igbeyawo.
Mat 22:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé: “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ pe àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ sí ibi àsè ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá. “Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’ “Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.” Àwọn ìyókù sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àbùkù sí wọn, wọ́n lù wọ́n pa. Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn. “Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà. Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’ Nítorí náà, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àsè ìyàwó sì kún fún àlejò.
Mat 22:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si dahùn, o si tún fi owe sọ̀rọ fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi ọba kan, ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rẹ̀. O si rán awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọ ipè awọn ti a ti pè tẹlẹ si ibi iyawo: ṣugbọn nwọn kò fẹ wá. O si tún rán awọn ọmọ-ọdọ miran, wipe, Ẹ wi fun awọn ti a pè pe, Wò o, mo se onjẹ mi tan: a pa malu ati gbogbo ẹran abọpa mi, a si ṣe ohun gbogbo tan: ẹ wá si ibi iyawo. Ṣugbọn nwọn ko fi pè nkan, nwọn ba tiwọn lọ, ọkan si ọ̀na oko rẹ̀, omiran si ọ̀na òwò rẹ̀: Awọn iyokù si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn ṣe àbuku si wọn, nwọn si lù wọn pa. Nigbati ọba si gbọ́ eyi, o binu: o si rán awọn ogun rẹ̀ lọ, o pa awọn apania wọnni run, o si kun ilu wọn. Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A se ase iyawo tan, ṣugbọn awọn ti a ti pè kò yẹ. Nitorina ẹ lọ si ọ̀na opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo. Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun.