Mat 15:7-11
Mat 15:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin agabagebe, otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti nyin, wipe, Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi. Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ. O si pè ijọ enia, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ki o si ye nyin; Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́.
Mat 15:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin alaiṣootọ! Òtítọ́ ni Aisaya ti sọtẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé, ‘Ọlọrun sọ pé: Ẹnu lásán ni àwọn eniyan wọnyi fi ń bọlá fún mi, ọkàn wọn jìnnà pupọ sí mi. Asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí, ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí ẹni pé òfin Ọlọrun ni.’ ” Ó wá pe àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́, kí ó sì ye yín. Kì í ṣe ohun tí ó ń wọ ẹnu ẹni lọ ni ó ń sọni di aláìmọ́, bíkòṣe ohun tí ó ń jáde láti ẹnu wá ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”
Mat 15:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé: “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni ìsìn wọn; nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ” Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín. Ènìyàn kò di ‘aláìmọ́’ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ní di ‘aláìmọ́.’ ”