MATIU 15

15
Àṣà Ìbílẹ̀ Àwọn Juu
(Mak 7:1-23)
1Nígbà náà ni àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá sọ́dọ̀ Jesu láti Jerusalẹmu, wọ́n bi í pé, 2“Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà tí àwọn baba wa fi lé wa lọ́wọ́? Nítorí wọn kì í wẹ ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.”
3Jesu dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀yin náà ṣe ń fi àṣà ìbílẹ̀ yín rú òfin Ọlọrun? 4Nítorí Ọlọrun sọ pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’; ati pé, ‘Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ burúkú sí baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á.’#a Eks 20:12; Diut 5:16; b Eks 21:17; Lef 20:9 5Ṣugbọn ẹ̀yin sọ pé, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé, ‘Mo ti fi ohun tí ò bá fi jẹ anfaani lára mi tọrẹ fún Ọlọrun,’ 6kò tún níláti bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀#15:6 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn fi gbolohun yìí kún un pé: ati ìyá rẹ̀. mọ́. Báyìí ni ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. 7Ẹ̀yin alaiṣootọ! Òtítọ́ ni Aisaya ti sọtẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé,
8‘Ọlọrun sọ pé:
Ẹnu lásán ni àwọn eniyan wọnyi fi ń bọlá fún mi,
ọkàn wọn jìnnà pupọ sí mi.
9Asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí,#Ais 29:13;
ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí ẹni pé òfin Ọlọrun ni.’ ”
10Ó wá pe àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́, kí ó sì ye yín. 11Kì í ṣe ohun tí ó ń wọ ẹnu ẹni lọ ni ó ń sọni di aláìmọ́, bíkòṣe ohun tí ó ń jáde láti ẹnu wá ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”
12Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ó bí wọn ninu?”
13Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi tí ń bẹ lọ́run kò bá gbìn ni a óo hú dànù. 14Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tí ó ń fọ̀nà hanni ni wọ́n. Bí afọ́jú bá ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn mejeeji yóo jìn sinu kòtò.”#Luk 6:39
15Peteru sọ fún un pé, “Túmọ̀ òwe yìí fún wa.”
16Jesu dá a lóhùn pé, “Kò ì tíì yé ẹ̀yin náà títí di ìwòyí? 17Kò ye yín pé ikùn ni gbogbo ohun tí eniyan bá fi sí ẹnu ń lọ ati pé eniyan óo tún yà á jáde? 18Ṣugbọn ohun tí eniyan bá sọ láti inú ọkàn rẹ̀ wá, èyí ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.#Mat 12:34 19Nítorí láti inú ọkàn ni èrò burúkú ti ń jáde wá: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe, olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ìsọkúsọ. 20Àwọn nǹkan wọnyi ni wọ́n ń sọ eniyan di aláìmọ́; kí eniyan jẹun láì wẹ ọwọ́ kò lè sọ eniyan di aláìmọ́.”
Igbagbọ Obinrin Ará Kenaani Kan
(Mak 7:24-30)
21Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tire ati Sidoni. 22Obinrin Kenaani kan tí ó ń gbé ibẹ̀ bá jáde, ó ń kígbe pé, “Ṣàánú mi, Oluwa, ọmọ Dafidi. Ẹ̀mí èṣù ní ń da ọdọmọbinrin mi láàmú.”
23Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sọ fún un pé, “Lé obinrin yìí lọ, nítorí ó ń pariwo tẹ̀lé wa lẹ́yìn.”
24Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.”
25Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.”
26Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!”
27Obinrin náà ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa. Ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti inú àwo oúnjẹ oluwa wọn.”
28Nígbà náà ni Jesu sọ fún un pé, “Obinrin yìí! Igbagbọ rẹ tóbi gidi. Kí ó rí fún ọ bí o ti fẹ́.” Ara ọdọmọbinrin rẹ̀ bá dá láti àkókò náà.
Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn
29Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀. 30Ọ̀pọ̀ eniyan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n gbé àwọn arọ wá, ati àwọn afọ́jú, àwọn amúkùn-ún ati àwọn odi, ati ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bá wò wọ́n sàn. 31Ẹnu ya àwọn eniyan, nígbà tí wọ́n rí i tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn amúkùn-ún di alára líle, tí àwọn arọ ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran. Wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun Israẹli.
Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan
(Mak 8:1-10)
32Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ ó ní, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi; wọn kò ní oúnjẹ mọ́. N kò fẹ́ tú wọn ká pẹlu ebi ninu, kí òòyì má baà gbé wọn lọ́nà.”
33Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Níbo ni a óo ti rí oúnjẹ ní aṣálẹ̀ yìí tí yóo yó àwọn eniyan tí ó pọ̀ tó báyìí?”
34Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?”
Wọ́n ní, “Meje, ati ẹja kéékèèké díẹ̀.”
35Jesu pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó nílẹ̀. 36Ó wá mú burẹdi meje náà ati àwọn ẹja náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù wọ́n, ó bá kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá pín wọn fún àwọn eniyan. 37Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó; wọ́n sì kó àjẹkù wọn jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ meje. 38Àwọn tí wọ́n jẹ oúnjẹ jẹ́ ẹgbaaji (4,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.
39Lẹ́yìn tí Jesu ti tú àwọn eniyan ká, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó bá lọ sí agbègbè Magadani.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 15: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀