Mat 15:29-30
Mat 15:29-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o wá si eti okun Galili, o gùn ori òke lọ, o si joko nibẹ̀. Ọpọ enia si tọ̀ ọ wá ti awọn ti amukun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ awọn miran, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o si mu wọn larada
Pín
Kà Mat 15Mat 15:29-30 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n gbé àwọn arọ wá, ati àwọn afọ́jú, àwọn amúkùn-ún ati àwọn odi, ati ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bá wò wọ́n sàn.
Pín
Kà Mat 15