Mat 15:16-19
Mat 15:16-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ? Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade? Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu
Mat 15:16-19 Yoruba Bible (YCE)
Jesu dá a lóhùn pé, “Kò ì tíì yé ẹ̀yin náà títí di ìwòyí? Kò ye yín pé ikùn ni gbogbo ohun tí eniyan bá fi sí ẹnu ń lọ ati pé eniyan óo tún yà á jáde? Ṣugbọn ohun tí eniyan bá sọ láti inú ọkàn rẹ̀ wá, èyí ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́. Nítorí láti inú ọkàn ni èrò burúkú ti ń jáde wá: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe, olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ìsọkúsọ.
Mat 15:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”? “Ẹyin kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde? Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.