Mat 11:25-30
Mat 11:25-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́. Gẹgẹ bẹ̃ na ni, Baba, nitori bẹ̀li o tọ́ li oju rẹ. Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun. Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ́, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin. Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Nitori àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ.
Mat 11:25-30 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni. “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún. “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀. Nítorí àjàgà mi tuni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.”
Mat 11:25-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún. “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”