Mat 10:17-25

Mat 10:17-25 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín. “Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là. Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé. “Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ. Ó tó fún ọmọ-ẹ̀yìn bí ó bá dàbí olùkọ́ rẹ̀. Ó tó fún ẹrú bí ó bá dàbí oluwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelisebulu, kí ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀!

Mat 10:17-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbèríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú Sinagọgu. Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ síwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà. Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín. “Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà. Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Israẹli já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé. “Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!