Mal 4:1
Mal 4:1 Bibeli Mimọ (YBCV)
SA kiye si i, ọjọ na mbọ̀, ti yio ma jó bi iná ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yio dabi akékù koriko: ọjọ na ti mbọ̀ yio si jo wọn run, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti kì yio fi kù gbòngbo tabi ẹka fun wọn.
Mal 4:1 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀ bí iná ìléru, tí àwọn agbéraga ati àwọn oníṣẹ́ ibi yóo jóná bíi koríko gbígbẹ. Ráúráú ni wọn óo jóná. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!
Mal 4:1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn.