Mal 4

4
Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀
1SA kiye si i, ọjọ na mbọ̀, ti yio ma jó bi iná ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yio dabi akékù koriko: ọjọ na ti mbọ̀ yio si jo wọn run, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti kì yio fi kù gbòngbo tabi ẹka fun wọn.
2Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo.
3Ẹnyin o si tẹ̀ awọn enia buburu mọlẹ: nitori nwọn o jasi ẽrú labẹ atẹlẹsẹ̀ nyin, li ọjọ na ti emi o dá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
4Ẹ ranti ofin Mose iranṣẹ mi, eyi ti mo pa li aṣẹ fun u ni Horebu fun gbogbo Israeli, pẹlu aṣẹ ati idajọ wọnni.
5Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà Oluwa, ati ọjọ ti o li ẹ̀ru to de:
6Yio si pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ọkàn awọn ọmọ si ti awọn baba wọn, ki emi ki o má ba wá fi aiye gégun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mal 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀