Luk 8:51-56
Luk 8:51-56 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Jesu si wọ̀ ile, kò jẹ ki ẹnikẹni wọle, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati baba on iya ọmọbinrin na. Gbogbo nwọn si sọkun, nwọn pohùnrere ẹkún rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ má sọkun mọ́; kò kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú. Nigbati o si sé gbogbo wọn mọ́ ode, o mu u li ọwọ́, o si wipe, Ọmọbinrin, dide. Ẹmí rẹ̀ si pada bọ̀, o si dide lọgan: o ni ki nwọn ki o fun u li onjẹ. Ẹnu si yà awọn õbi rẹ̀: ṣugbọn o kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe wi fun ẹnikan li ohun ti a ṣe.
Luk 8:51-56 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu dé ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi Peteru, Johanu ati Jakọbu, baba ati ìyá ọmọ náà. Gbogbo àwọn eniyan ń sunkún, wọ́n ń dárò nítorí ọmọ náà. Ṣugbọn Jesu ní, “Ẹ má sunkún mọ́, nítorí ọmọ náà kò kú, ó ń sùn ni.” Ńṣe ni wọ́n ń fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. Jesu fa ọmọ náà lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ọmọ, dìde.” Ẹ̀mí rẹ̀ bá pada sinu rẹ̀, ni ó bá dìde lẹsẹkẹsẹ. Jesu bá sọ fún wọn pé kí wọn fún un ní oúnjẹ. Ẹnu ya àwọn òbí ọmọ náà. Ṣugbọn ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.
Luk 8:51-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà. Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú. Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!” Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ. Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.