Luk 8:43-48
Luk 8:43-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá, O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ. Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi? Jesu si wipe, Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi: nitoriti emi mọ̀ pe aṣẹ jade lara mi. Nigbati obinrin na si mọ̀ pe on ko farasin, o warìri, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ fun u li oju awọn enia gbogbo nitori ohun ti o ṣe, ti on fi fi ọwọ́ tọ́ ọ, ati bi a ti mu on larada lojukanna. O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, tújuka: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia.
Luk 8:43-48 Yoruba Bible (YCE)
Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn. Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀. Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?” Ṣugbọn Jesu tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí sẹ́ẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti ara mi jáde.” Nígbà tí obinrin náà rí i pé kò ṣe é fi pamọ́, ó bá jáde, ó ń gbọ̀n. Ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó bá sọ ìdí tí òun ṣe fọwọ́ kàn án lójú gbogbo eniyan ati bí òun ṣe rí ìwòsàn lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá wí fún un pé, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá, máa lọ ní alaafia.”
Luk 8:43-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ. Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?” Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.” Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà. Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá; máa lọ ní Àlàáfíà!”