Luk 8:26-39

Luk 8:26-39 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili. Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji. Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró. (Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.) Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? Ó si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ. Nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe rán wọn lọ sinu ibu. Agbo ẹlẹdẹ pipọ si mbẹ nibẹ̀ ti njẹ li ori òke: nwọn si bẹ̀ ẹ ki o jẹ ki awọn wọ̀ inu wọn lọ. O si jọwọ wọn. Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi. Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na. Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn. Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada. Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin. Njẹ ọkunrin na ti ẹmi èṣu jade kuro lara rẹ̀, o bẹ̀ ẹ ki on ki o le ma bá a gbé: ṣugbọn Jesu rán a lọ, wipe, Pada lọ ile rẹ, ki o si sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọ bi o ti pọ̀ to. O si lọ, o si nròhin já gbogbo ilu na bi Jesu ti ṣe ohun nla fun on to.

Luk 8:26-39 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Geraseni tí ó wà ní òdì keji òkun tí ó dojú kọ ilẹ̀ Galili. Bí ó ti bọ́ sí èbúté, ọkunrin kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú ìlú wá pàdé rẹ̀. Ó ti pẹ́ tí ó ti fi aṣọ kanra gbẹ̀yìn, kò sì lè gbé inú ilé mọ́, àfi ní itẹ́ òkú. Nígbà tí ó rí Jesu, ó kígbe, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó kébòòsí pé, “Kí ni ó pa èmi ati ìwọ pọ̀, Jesu, ọmọ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo? Mo bẹ̀ ọ́ má dá mi lóró!” Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò ninu ọkunrin yìí. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ní í máa ń dé sí i. Wọn á fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́, wọn á tún kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Ṣugbọn jíjá ni yóo já ohun tí wọ́n fi dè é, ni yóo bá sálọ sinu aṣálẹ̀. Jesu bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje,” Nítorí àwọn ẹ̀mí èṣù tí ó ti wọ inú rẹ̀ pọ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá bẹ Jesu pé kí ó má lé àwọn lọ sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ lórí òkè. Àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí àwọn kó sí inú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà. Ó bá gbà fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi. Nígbà tí àwọn tí ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ ròyìn ní ìlú ati ní ìgbèríko. Àwọn eniyan bà jáde láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀, tí ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, ojú rẹ̀ sì wálẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan. Àwọn tí ó mọ̀ bí ara ọkunrin náà ti ṣe dá ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Gbogbo àwọn eniyan agbègbè Geraseni bá bẹ Jesu pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Ó bá tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó pada sí ibi tí ó ti wá. Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní, “Pada lọ sí ilé rẹ, kí o lọ ròyìn ohun tí Ọlọrun ṣe fún ọ.” Ni ọkunrin náà bá ń káàkiri gbogbo ìlú, ó ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un.

Luk 8:26-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili. Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì. Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” (Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkúgbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì ja gbogbo ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù). Jesu sì bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó sì dáhùn pé, “Légíónì,” nítorí ẹ̀mí èṣù púpọ̀ ni ó wa nínú rẹ. Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì gba fún wọn. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀. Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà. Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jesu wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n. Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gadara yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó si kúrò. Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé, “Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.” Ó sì lọ, o sì ń ròyìn ka gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá fún òun tó.