Luk 8:2-3
Luk 8:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Maria tí a ń pè ní Magdalene, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò. Àti Joanna aya Kuṣa tí í ṣe ìríjú Herodu, àti Susana, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn.
Luk 8:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro, Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.
Luk 8:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obinrin kan tí Jesu ti wòsàn kúrò ninu ẹ̀mí èṣù ati àìlera ń bá a kiri. Ninu wọn ni Maria tí à ń pè ní Magidaleni wà, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje jáde ninu rẹ̀, ati Joana iyawo Kusa, ọmọ-ọ̀dọ̀ Hẹrọdu, ati Susana ati ọpọlọpọ àwọn mìíràn. Àwọn yìí ni wọ́n ń fi ohun ìní wọn bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ bùkátà wọn.