Luk 7:4-6
Luk 7:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si de ọdọ Jesu, nwọn fi itara bẹ̀ ẹ, wipe, O yẹ li ẹniti on iba ṣe eyi fun: Nitoriti o fẹran orilẹ-ede wa, o si ti kọ́ sinagogu kan fun wa. Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi
Luk 7:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún, nítorí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, òun fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ ilé ìpàdé fún wa.” Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀.
Luk 7:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún: Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi