LUKU 7

7
Jesu Wo Iranṣẹ Ọ̀gágun Kan Sàn
(Mat 8:5-13)
1Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ. 2Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un. 3Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn. 4Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún, 5nítorí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, òun fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ ilé ìpàdé fún wa.”
6Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀. 7Òun ni kò jẹ́ kí èmi fúnra mi wá sọ́dọ̀ rẹ. Ṣugbọn sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. 8Nítorí èmi náà jẹ́ ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ. Mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ Yóo lọ ni. Bí mo bá sì sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ Yóo wá ni. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ Yóo ṣe é ni.”
9Nígbà tí Jesu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹnu yà á. Ó bá yipada sí àwọn eniyan tí ó ń tẹ̀lé e, ó ní, “Mò ń sọ fun yín, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!”
10Nígbà tí àwọn tí ọ̀gágun rán pada dé ilé, wọ́n rí ẹrú náà tí ara rẹ̀ ti dá.
Jesu Jí Ọmọ Opó Kan Dìde Ní Naini
11Láìpẹ́ lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Naini. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ eniyan ń bá a lọ. 12Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà. 13Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.” 14Ni ó bá lọ, ó fi ọwọ́ kan pósí. Àwọn tí wọ́n gbé pósí bá dúró. Ó bá sọ pé, “Ọdọmọkunrin, mo sọ fún ọ, dìde.” 15Ọdọmọkunrin tí ó ti kú yìí bá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Jesu bà fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
16Ẹ̀rù ba gbogbo eniyan, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun, wọ́n ní, “Wolii ńlá ti dìde ni ààrin wa. Ọlọrun ti bojúwo àwọn eniyan rẹ̀.”
17Ìròyìn ohun tí ó ṣe yìí tàn ká gbogbo Judia ati gbogbo agbègbè ibẹ̀.
Johanu Ranṣẹ Sí Jesu
(Mat 11:2-19)
18Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ròyìn gbogbo nǹkan wọnyi fún un. Johanu bá pe meji ninu wọn, 19ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”
20Nígbà tí àwọn ọkunrin náà dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ní, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó rán wa sí ọ láti bi ọ́ pé, ‘Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?’ ”
21Ní àkókò náà, Jesu ń wo ọpọlọpọ eniyan sàn ninu àìsàn ati àrùn. Ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọpọlọpọ àwọn afọ́jú ni ó jẹ́ kí wọ́n ríran. 22Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ ohun tí ẹ rí ati ohun tí ẹ gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran; àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́; àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde; à ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.#a Ais 35:5-6; b Ais 61:1 23Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”
24Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ Johanu lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ nípa Johanu fún àwọn eniyan. Ó ní, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Igi légbélégbé tí afẹ́fẹ́ ń tì sọ́tùn-ún, ati sósì ni bí? 25Kí ni ẹ jáde lọ wò? Ọkunrin tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye ni bí? Bí ẹ bá fẹ́ rí àwọn tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba. 26Àní, kí ni ẹ lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ! 27Òun ni a kọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ, òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’#Mal 3:1 28Mo sọ fun yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni jákèjádò ayé yìí tí ó ṣe pataki ju Johanu lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jùlọ ninu ìjọba ọ̀run ṣe pataki jù ú lọ.”
29Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan gbọ́, tí ó fi mọ́ àwọn agbowó-odè pàápàá, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun, wọ́n lọ ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ètò ìrìbọmi Johanu. 30Ṣugbọn àwọn Farisi ati àwọn amòfin kọ ìlànà Ọlọrun fún wọn, wọn kò ṣe ìrìbọmi ti Johanu.#Mat 21:32; Luk 3:12
31Jesu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ta ni èmi ìbá fi àwọn eniyan òde òní wé? Ta ni kí a wí pé wọ́n jọ? 32Wọ́n jọ àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà. Àwọn kan ń pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé, ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, A sun rárà òkú fun yín, ẹ kò sunkún.’ 33Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi dé, kò jẹ, kò mu, ẹ sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’ 34Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu, ẹ ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ 35Sibẹ a mọ̀ pé ọgbọ́n Ọlọrun tọ̀nà nípa ìṣesí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”
Jesu Dárí Ji Obinrin Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kan
36Ọ̀kan ninu àwọn Farisi pe Jesu pé kí ó wá bá òun jẹun. Jesu bà lọ sí ilé Farisi yìí lọ jẹun. 37Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́, 38ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀.#Mat 26:7; Mak 14:3; Joh 12:3 39Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
40Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.”
Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.”
41Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka. 42Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà ati san gbèsè wọn, ẹni tí ó yá wọn lówó bùn wọ́n ní owó náà. Ninu àwọn mejeeji, ta ni yóo fẹ́ràn rẹ̀ jù?”
43Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.”
Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.” 44Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún. 45O kò fi ìfẹnukonu kí mi. Ṣugbọn obinrin yìí kò dẹ́kun láti fi ẹnu kan ẹsẹ̀ mi láti ìgbà tí mo ti wọ ilé. 46O kò fi òróró kùn mí lórí. Ṣugbọn obinrin yìí fi òróró olóòórùn dídùn kùn mí lẹ́sẹ̀. 47Nítorí èyí, mo sọ fún ọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í, nítorí ó ní ìfẹ́ pupọ. Ṣugbọn ẹni tí a bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀ jì, ìfẹ́ díẹ̀ ni yóo ní.”
48Ó bá sọ fún obinrin náà pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
49Àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun bà bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan?”
50Jesu bá sọ fún obinrin náà pé, “Igbagbọ rẹ ti gbà ọ́ là. Máa lọ ní alaafia.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LUKU 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀