Luk 7:36-50

Luk 7:36-50 Bibeli Mimọ (YBCV)

Farisi kan si rọ̀ ọ ki o wá ba on jẹun. O si wọ̀ ile Farisi na lọ o si joko lati jẹun. Si kiyesi i, obinrin kan wà ni ilu na, ẹniti iṣe ẹlẹṣẹ, nigbati o mọ̀ pe Jesu joko njẹun ni ile Farisi, o mu oruba alabastar ororo ikunra wá, O si duro tì i lẹba ẹsẹ rẹ̀ lẹhin, o nsọkun, o si bẹ̀rẹ si ifi omije wẹ̀ ẹ li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù u nù, o si nfi ẹnu kò o li ẹsẹ, o si nfi ororo kùn wọn. Nigbati Farisi ti o pè e si ri i, o wi ninu ara rẹ̀ pe, ọkunrin yi iba ṣe woli, iba mọ̀ ẹni ati irú ẹniti obinrin yi iṣe ti nfi ọwọ́ kan a: nitori ẹlẹṣẹ ni. Jesu si dahùn wi fun u pe, Simoni, Mo ni ohun kan isọ fun ọ. O si dahùn wipe, Olukọni, mã wi. Onigbese kan wà ti o ni ajigbese meji: ọkan jẹ ẹ ni ẹdẹgbẹta owo idẹ, ekeji si jẹ ẹ ni adọta. Nigbati nwọn kò si ni ti nwọn o san, o darijì awọn mejeji. Wi, ninu awọn mejeji tani yio fẹ ẹ jù? Simoni dahùn o si wipe, mo ṣebi ẹniti o darijì jù ni. O si wi fun u pe, O wi i 're. O si yipada si obinrin na, o wi fun Simoni pe, Iwọ ri obinrin yi? Emi wọ̀ ile rẹ, omi wiwẹ̀ ẹsẹ iwọ kò fifun mi: ṣugbọn on, omije li o fi nrọjo si mi li ẹsẹ, irun ori rẹ̀ li o fi nnù wọn nù. Ifẹnukonu iwọ kò fi fun mi: ṣugbọn on, nigbati mo ti wọ̀ ile, ko dabọ̀ ẹnu ifi kò mi li ẹsẹ. Iwọ kò fi oróro pa mi li ori: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ. Njẹ mo wi fun ọ, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o pọ̀ jì i; nitoriti o ni ifẹ pipọ: ẹniti a si dari diẹ jì, on na li o ni ifẹ diẹ. O si wi fun u pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. Awọn ti o bá a joko njẹun si bẹ̀rẹ si irò ninu ara wọn pe, Tali eyi ti ndari ẹ̀ṣẹ jì-ni pẹlu? O si dahùn wi fun obinrin na pe, Igbagbọ́ rẹ gbà ọ là; mã lọ li alafia.

Luk 7:36-50 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀kan ninu àwọn Farisi pe Jesu pé kí ó wá bá òun jẹun. Jesu bà lọ sí ilé Farisi yìí lọ jẹun. Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́, ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀. Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.” Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.” Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka. Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà ati san gbèsè wọn, ẹni tí ó yá wọn lówó bùn wọ́n ní owó náà. Ninu àwọn mejeeji, ta ni yóo fẹ́ràn rẹ̀ jù?” Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.” Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún. O kò fi ìfẹnukonu kí mi. Ṣugbọn obinrin yìí kò dẹ́kun láti fi ẹnu kan ẹsẹ̀ mi láti ìgbà tí mo ti wọ ilé. O kò fi òróró kùn mí lórí. Ṣugbọn obinrin yìí fi òróró olóòórùn dídùn kùn mí lẹ́sẹ̀. Nítorí èyí, mo sọ fún ọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í, nítorí ó ní ìfẹ́ pupọ. Ṣugbọn ẹni tí a bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀ jì, ìfẹ́ díẹ̀ ni yóo ní.” Ó bá sọ fún obinrin náà pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun bà bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan?” Jesu bá sọ fún obinrin náà pé, “Igbagbọ rẹ ti gbà ọ́ là. Máa lọ ní alaafia.”

Luk 7:36-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun. Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá, Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n. Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.” Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.” “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta. Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?” Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.” Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù. Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀. Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀. Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.” Ó sì wí fún un pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!” Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?” Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là; máa lọ ní Àlàáfíà.”