Luk 7:1-3
Luk 7:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o si pari gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ li eti awọn enia, o wọ̀ Kapernaumu lọ. Ọmọ-ọdọ balogun ọrún kan, ti o ṣọwọn fun u, o ṣaisàn, o nkú lọ. Nigbati o si gburó Jesu, o rán awọn agbagba Ju si i, o mbẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá mu ọmọ-ọdọ on larada.
Pín
Kà Luk 7Luk 7:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ. Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un. Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn.
Pín
Kà Luk 7Luk 7:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ. Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.
Pín
Kà Luk 7