Luk 22:31-53
Luk 22:31-53 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú. O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi. O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan. Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin. Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to. Ó si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò. Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn? Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn? Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù. Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn. Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá? Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.

Luk 22:31-53 Yoruba Bible (YCE)
“Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.” Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!” Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?” Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!” Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan. Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.” Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.” Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!” Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.” Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.] Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.” Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?” Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?” Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san. Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá? Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.”
Luk 22:31-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.” Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.” Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?” Wọ́n sì wí pé, “Rárá!” Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò-owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ọ̀kan. Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.” Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!” Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.” Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀. Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Jesu sì wí fún un pé, “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?” Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?” Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn. Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá? Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.”