“Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.”
Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.”
Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”
Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?”
Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!”
Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan. Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.”
Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.”
Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!”
Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]
Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?”
Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?” Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún.
Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san.
Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá? Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.”