Luk 20:19-47

Luk 20:19-47 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọna ati mu u ni wakati na; ṣugbọn nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitoriti nwọn mọ̀ pe, o pa owe yi mọ wọn. Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ. Nwọn si bi i, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe, iwọ a ma sọrọ fun ni, iwọ a si ma kọ́-ni bi o ti tọ, bẹ̃ni iwọ kì iṣojuṣaju ẹnikan ṣugbọn iwọ nkọ́-ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ. O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni. O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́. Awọn Sadusi kan si tọ̀ ọ wá, awọn ti nwọn nwipe ajinde okú kò si: nwọn si bi i, Wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, li ailọmọ, ti o li aya, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe iru dide fun arakunrin rẹ̀. Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: ekini gbé iyawo, o si kú li ailọmọ. Ekeji si ṣu u lopó, on si kú li ailọmọ. Ẹkẹta si ṣu u lopó; gẹgẹ bẹ̃ si li awọn mejeje pẹlu: nwọn kò si fi ọmọ silẹ, nwọn si kú. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. Njẹ li ajinde okú, aya titani yio ha ṣe ninu wọn? nitori awọn mejeje li o sá ni i li aya. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Awọn ọmọ aiye yi a ma gbeyawo, nwọn a si ma fà iyawo fun-ni. Ṣugbọn awọn ti a kà yẹ lati jogún aiye na, ati ajinde kuro ninu okú, nwọn kì igbeyawo, nwọn kì si ifà iyawo fun-ni: Nitori nwọn kò le kú mọ́; nitoriti nwọn ba awọn angẹli dọgba; awọn ọmọ Ọlọrun si ni nwọn, nitori nwọn di awọn ọmọ ajinde. Niti pe a njí awọn okú dide, Mose tikararẹ̀ si ti fihàn ni igbẹ́, nigbati o pè Oluwa ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Bẹni on kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye: nitori gbogbo wọn wà lãye fun u. Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe da a lohùn, wipe, Olukọni iwọ wi rere. Nwọn kò si jẹ bi i lẽre òrọ kan mọ́. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀? O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.

Luk 20:19-47 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn akọ̀wé ati àwọn olórí alufaa gbèrò láti mú un ní wakati náà, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́; ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ ọ. Wọ́n rán àwọn amí kí wọ́n ṣe bí eniyan rere, kí wọ́n lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kí wọn wá fi lé gomina lọ́wọ́, kí gomina dá sẹ̀ría fún un. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé tààrà ni ò ń sọ̀rọ̀, tí o sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. O kì í wo ojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. Ṣugbọn pẹlu òtítọ́ ni ò ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun. Ṣé ó tọ́ fún wa láti san owó-orí fún Kesari, àbí kò tọ́?” Ṣugbọn ó ti mọ ẹ̀tàn wọn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fi owó fadaka kan hàn mí.” Ó bá bi wọ́n léèrè pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ti ara rẹ̀ yìí?” Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.” Ó bá wí fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́. Àwọn kan ninu àwọn Sadusi bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọn kò gbà pé òkú kan a tún máa jinde.) Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, Mose pàṣẹ fún wa pé bí eniyan bá ní iyawo, bí ó bá kú láìní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú iyawo rẹ̀ lópó, kí ó ní ọmọ lórúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà. Ekinni gbé iyawo, ó kú láìní ọmọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ekeji. Ẹkẹta náà ṣú u lópó. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣe, wọ́n kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obinrin náà alára wá kú. Ní ọjọ́ ajinde, ti ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ló ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn eniyan ayé yìí ni wọ́n ń gbeyawo, tí wọn ń fi ọmọ fọ́kọ. Ṣugbọn àwọn tí a kà yẹ fún ayé tí ó ń bọ̀, nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò ní máa gbeyawo, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní máa fọmọ fọ́kọ. Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde. Ó dájú pé a jí àwọn òkú dìde nítorí ohun tí Mose kọ ninu ìtàn ìgbẹ́ tí ń jóná, nígbà tí ó sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun ti Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, ti àwọn alààyè ni; nítorí pé gbogbo wọn ni ó wà láàyè fún Ọlọrun.” Àwọn kan ninu àwọn amòfin dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, o wí ire!” Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́. Jesu bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni wọ́n ṣe ń pe Mesaya ní ọmọ Dafidi? Nítorí Dafidi sọ ninu ìwé Orin Dafidi pé, ‘Oluwa wí fún oluwa mi pé: Jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’ Nígbà tí Dafidi pè é ní Oluwa, báwo ni ó ti ṣe tún jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ní etí gbogbo àwọn eniyan, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè. Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.”

Luk 20:19-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn. Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́. Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?” Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́. Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.” Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.” Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’ Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”