Luk 20:19-47

Luk 20:19-47 YBCV

Awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọna ati mu u ni wakati na; ṣugbọn nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitoriti nwọn mọ̀ pe, o pa owe yi mọ wọn. Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ. Nwọn si bi i, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe, iwọ a ma sọrọ fun ni, iwọ a si ma kọ́-ni bi o ti tọ, bẹ̃ni iwọ kì iṣojuṣaju ẹnikan ṣugbọn iwọ nkọ́-ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ. O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni. O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́. Awọn Sadusi kan si tọ̀ ọ wá, awọn ti nwọn nwipe ajinde okú kò si: nwọn si bi i, Wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, li ailọmọ, ti o li aya, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe iru dide fun arakunrin rẹ̀. Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: ekini gbé iyawo, o si kú li ailọmọ. Ekeji si ṣu u lopó, on si kú li ailọmọ. Ẹkẹta si ṣu u lopó; gẹgẹ bẹ̃ si li awọn mejeje pẹlu: nwọn kò si fi ọmọ silẹ, nwọn si kú. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. Njẹ li ajinde okú, aya titani yio ha ṣe ninu wọn? nitori awọn mejeje li o sá ni i li aya. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Awọn ọmọ aiye yi a ma gbeyawo, nwọn a si ma fà iyawo fun-ni. Ṣugbọn awọn ti a kà yẹ lati jogún aiye na, ati ajinde kuro ninu okú, nwọn kì igbeyawo, nwọn kì si ifà iyawo fun-ni: Nitori nwọn kò le kú mọ́; nitoriti nwọn ba awọn angẹli dọgba; awọn ọmọ Ọlọrun si ni nwọn, nitori nwọn di awọn ọmọ ajinde. Niti pe a njí awọn okú dide, Mose tikararẹ̀ si ti fihàn ni igbẹ́, nigbati o pè Oluwa ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Bẹni on kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye: nitori gbogbo wọn wà lãye fun u. Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe da a lohùn, wipe, Olukọni iwọ wi rere. Nwọn kò si jẹ bi i lẽre òrọ kan mọ́. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀? O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.

Related Videos