Luk 18:16-17
Luk 18:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.
Pín
Kà Luk 18Luk 18:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.”
Pín
Kà Luk 18Luk 18:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
Pín
Kà Luk 18