LUKU 18

18
Òwe Nípa Opó Kan ati Adájọ́
1Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀. 2Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí. 3Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’ 4Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan, 5ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ”
6Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí! 7Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn?#Sir 35:19 8Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?”
Òwe Nípa Farisi Kan ati Agbowó-odè
9Ó wá pa òwe yìí fún àwọn tí wọ́n gbójú lé ara wọn bí olódodo, tí wọn ń kẹ́gàn gbogbo àwọn eniyan yòókù. 10Ó ní, “Àwọn ọkunrin meji kan gòkè lọ sí Tẹmpili wọ́n lọ gbadura. Ọ̀kan jẹ́ Farisi, ekeji jẹ́ agbowó-odè.
11“Èyí Farisi dá dúró, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, ‘Ọlọrun, mo dúpẹ́ pé ń kò dàbí àwọn yòókù, àwọn oníwọ̀ra, alaiṣootọ, alágbèrè. N kò tilẹ̀ dàbí agbowó-odè yìí. 12Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’
13“Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’#Man 8 14Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”#Mat 23:12; Luk 14:11
Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde
(Mat 19:13-15; Mak 10:13-16)
15Àwọn eniyan ń gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá, pé kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tí wọ́n gbé wọn wá wí. 16Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. 17Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.”
18Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”
19Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo. 20Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ”#a Eks 20:14; Diut 5:18 b Eks 20:13; Diut 5:17; d Eks 20:15; Diut 5:19 e Eks 20:16; Diut 5:20 ẹ Eks 20:12; Diut 5:16
21Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.”
22Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.” 23Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bàjẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.
24Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun. 25Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun.”
26Àwọn tí ó gbọ́ ní, “Ta wá ni a óo gbà là?”
27Ó dáhùn pé, “Ohun tí kò ṣeéṣe fún eniyan, ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”
28Peteru sọ fún un pé, “Wò ó ná! Àwa ti fi ohun gbogbo tí a ní sílẹ̀, a sì ti ń tẹ̀lé ọ.”
29Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí ẹni tí ó fi ilé, iyawo, arakunrin, òbí tabi ọmọ sílẹ̀, nítorí ti ìjọba Ọlọrun, 30tí kò ní rí ìlọ́po-ìlọ́po gbà ní ayé yìí, yóo sì ní ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.”
Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta
(Mat 20:17-19; Mak 10:32-34)
31Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ. 32Nítorí a óo fi í lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn óo fi ṣe ẹ̀sín, wọn óo fi àbùkù kàn án, wọn óo tutọ́ sí i lára. 33Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.”
34Ṣugbọn ohun tí ó sọ kò yé wọn. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sápamọ́ fún wọn. Wọn kò mọ ohun tí ó ń sọ.
Jesu Wo Afọ́jú Alágbe Sàn Ní Jẹriko
(Mat 20:29-34; Mak 10:46-52)
35Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe. 36Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń kọjá lọ, ó wádìí ohun tí ó dé.
37Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”
38Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!”
39Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú mi.”
40Jesu bá dúró, ó ní kí wọ́n lọ fà á lọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí ó dé, Jesu bi í pé, 41“Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”
Ó dáhùn pé, “Alàgbà, mo fẹ́ tún ríran ni!”
42Jesu sọ fún un pé, “Ǹjẹ́, ríran. Igbagbọ rẹ mú ọ lára dá.”
43Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LUKU 18: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa