Luk 18:1-8
Luk 18:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si pa owe kan fun wọn nitori eyiyi pe, o yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ̀; Wipe, Onidajọ́ kan wà ni ilu kan, ti kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti kò si ṣe ojusaju enia: Opó kan si wà ni ilu na; o si ntọ̀ ọ wá, wipe, Gbẹsan mi lara ọtá mi. Kò si ṣu si i nigba sã kan: ṣugbọn nikẹhin o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi emi kò tilẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ti emi ko si ṣe ojuṣãju enia; Ṣugbọn nitoriti opó yi nyọ mi lẹnu, emi o gbẹsan rẹ̀, ki o má ba fi wíwa rẹ̀ nigbakugba da mi lagãra. Oluwa si wipe, Ẹ gbọ́ bi alaiṣõtọ onidajọ ti wi. Ọlọrun kì yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ̀, ti nfi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn? Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?
Luk 18:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀. Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí. Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’ Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan, ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ” Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí! Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?”
Luk 18:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀; Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn. Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!’ “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn: ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn, Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkúgbà dá mi lágara.’ ” Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí! Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn? Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”