Luk 17:15-19
Luk 17:15-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo. O si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o ndupẹ li ọwọ rẹ̀: ara Samaria ni on si iṣe. Jesu si dahùn wipe, Awọn mẹwa ki a ṣo di mimọ́? Awọn mẹsan iyokù ha dà? A ko ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikọse alejò yi? O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.
Luk 17:15-19 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ọ̀kan ninu wọn rí i pé ara òun ti dá, ó pada, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun pẹlu ohùn gíga. Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni. Jesu bèèrè pé, “Ṣebí àwọn mẹ́wàá ni mo mú lára dá. Àwọn mẹsan-an yòókù dà? Kò wá sí ẹni tí yóo pada wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, àfi àlejò yìí?” Jesu bá sọ fún un pé, “Dìde, máa lọ. Igbagbọ rẹ ni ó mú ọ lára dá.”
Luk 17:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe. Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”