Luk 17:1-4
Luk 17:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ko le ṣe ki ohun ikọsẹ̀ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ̀ de. Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ̀. Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i. Bi o ba si ṣẹ̀ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ̀ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari jì i.
Luk 17:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “A kò lè ṣàì rí ohun ìkọsẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó ti ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀ gbé! Ó sàn fún un kí á so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, kí á jù ú sinu òkun jù pé kí ó mú ohun ìkọsẹ̀ bá ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi. Ẹ ṣọ́ra yín! “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, bá a wí; bí ó bá ronupiwada, dáríjì í. Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ẹẹmeje ní ọjọ́ kan, tí ó yipada sí ọ lẹẹmeje, tí ó bẹ̀ ọ́ pé, ‘Jọ̀ọ́ má bínú,’ dáríjì í.”
Luk 17:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”